bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 5
Job 5
Yoruba 2010
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 6 →
1
“Pe ẹnìkan nisinsinyii; ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni dá ọ lóhùn? Ẹni mímọ́ wo ni o lè tọ̀ lọ?
2
Dájúdájú ibinu a máa pa òmùgọ̀, owú jíjẹ a sì máa pa aláìmọ̀kan.
3
Mo ti rí òmùgọ̀ tí ó fìdí múlẹ̀, ṣugbọn lójijì, ibùgbé rẹ̀ di ìfibú.
4
Kò sí ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n di àtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹnubodè, kò sì sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n là.
5
Àwọn tí ebi ń pa níí jẹ ìkórè oko rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrin ẹ̀gún ni ó ti mú un jáde, àwọn olójúkòkòrò a sì máa wá ohun ìní rẹ̀ kiri.
6
Ìṣòro kì í hù láti inú erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìyọnu kì í ti inú ilẹ̀ jáde.
7
A bí eniyan sinu wahala bí ẹ̀ta iná tí ń ta sókè.
8
“Ní tèmi, n óo máa wá OLUWA, n óo fọ̀rọ̀ mi lé Ọlọrun lọ́wọ́;
9
ẹni tíí ṣe ohun ńlá tí eniyan kò lè rídìí, ati àwọn ohun ìyanu tí kò lóǹkà.
10
A máa rọ òjò sórí ilẹ̀, a sì máa bomi rin oko.
11
A máa gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga, a sì máa pa àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ mọ́.
12
A máa da ète àwọn alárèékérekè rú, kí wọn má baà lè yọrí ètekéte wọn.
13
Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n ninu àrékérekè wọn; ó sì mú ète àwọn ẹlẹ́tàn wá sópin.
14
Òkùnkùn bò wọ́n ní ọ̀sán gangan, wọ́n ń fọwọ́ tálẹ̀ lọ́sàn-án bí ẹnipé òru ni.
15
Ṣugbọn Ọlọrun gba aláìníbaba kúrò lọ́wọ́ wọn, ó gba àwọn aláìní kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára.
16
Nítorí náà, ìrètí ń bẹ fún talaka, a sì pa eniyan burúkú lẹ́nu mọ́.
17
“Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí Ọlọrun bá bá wí, nítorí náà, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olodumare.
18
Ó ń ṣá ni lọ́gbẹ́, ṣugbọn ó tún ń dí ọgbẹ́ ẹni. Ó ń pa ni lára, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ ló tún fi ń ṣe ìwòsàn.
19
Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ìnira lọpọlọpọ ìgbà, bí ibi ń ṣubú lu ara wọn, kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ.
20
Ní àkókò ìyàn, yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú. Ní àkókò ogun, yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.
21
Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gàn, o kò ní bẹ̀rù nígbà tí ìparun bá dé.
22
Ninu ìparun ati ìyàn, o óo máa rẹ́rìn-ín, o kò ní bẹ̀rù àwọn ẹranko ìgbẹ́.
23
O kò ní kan àwọn òkúta ninu oko rẹ, àwọn ẹranko igbó yóo wà ní alaafia pẹlu rẹ.
24
O óo máa gbé ilé rẹ ní àìséwu. Nígbà tí o bá ka ẹran ọ̀sìn rẹ, kò ní dín kan.
25
Àwọn arọmọdọmọ rẹ yóo pọ̀, bí ewéko ninu pápá oko.
26
O óo di arúgbó kí o tó kú, gẹ́gẹ́ bí ọkà tií gbó kí á tó kó o wá síbi ìpakà.
27
Wò ó! A ti wádìí àwọn nǹkan wọnyi, òtítọ́ ni wọ́n. Gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni.”
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42