bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 40
Job 40
Yoruba 2010
← Chapter 39
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 41 →
1
OLUWA tún sọ fún Jobu pé,
2
“Ṣé ẹni tí ń bá eniyan rojọ́ lè bá Olodumare rojọ́? Kí ẹni tí ń bá Ọlọrun jiyàn dáhùn.”
3
Nígbà náà ni Jobu dá OLUWA lóhùn, ó ní:
4
“OLUWA, kí ni mo jámọ́, tí n óo fi dá ọ lóhùn? Nítorí náà, mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
5
Mo ti sọ̀rọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ, n kò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.”
6
Nígbà náà ni OLUWA tún bá Jobu sọ̀rọ̀ láti inú ìjì líle, ó ní,
7
“Múra gírí bí ọkunrin, mo ní ìbéèrè láti bi ọ́, o óo sì dá mi lóhùn.
8
Ṣé o fẹ́ sọ pé mò ń ṣe àìdára ni? O fẹ́ dá mi lẹ́bi kí á lè dá ọ láre?
9
Ṣé o lágbára bí èmi Ọlọrun, àbí o lè sán wàá bí ààrá, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀?
10
Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fi ọlá ati ìyìn ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́, kí o sì fi ògo ati ẹwà bo ara rẹ bí aṣọ.
11
Fi ibinu rẹ hàn, wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
12
Wo gbogbo àwọn agbéraga, kí o sì sọ wọ́n di yẹpẹrẹ, rún àwọn ẹni ibi mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13
Bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ papọ̀, dì wọ́n ní ìgbèkùn sí ipò òkú.
14
Nígbà náà ni n óo gbà pé, agbára rẹ lè fún ọ ní ìṣẹ́gun.
15
“Wo Behemoti, ẹran ńlá inú omi, tí mo dá gẹ́gẹ́ bí mo ti dá ọ, koríko ni ó ń jẹ bíi mààlúù!
16
Wò ó bí ó ti lágbára tó! Ati irú okun tí awọ inú rẹ̀ ní.
17
Ìrù rẹ̀ dúró ṣánṣán bí igi kedari, gbogbo iṣan itan rẹ̀ dì pọ̀.
18
Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá idẹ, ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí irin.
19
“Ó wà lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí èmi Ọlọrun dá, sibẹ ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìkan ló lè pa á.
20
Orí àwọn òkè ni ó ti ń rí oúnjẹ jẹ, níbi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti ń ṣeré.
21
Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lotusi, lábẹ́ ọ̀pá ìyè ninu ẹrẹ̀.
22
Igi lotusi ni ó ń ṣíji bò ó, igi tí ó wà létí odò yí i ká.
23
Kò náání ìgbì omi, kò bẹ̀rù bí odò Jọdani tilẹ̀ ru dé bèbè rẹ̀.
24
Ṣé eniyan lè fi ìwọ̀ mú un? Tabi kí á fi ọ̀kọ̀ lu ihò sí imú rẹ̀?
← Chapter 39
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 41 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42