bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 8
Job 8
Yoruba 2010
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 9 →
1
Bilidadi ará Ṣuha dáhùn pé,
2
“O óo ti sọ irú ọ̀rọ̀ wọnyi pẹ́ tó, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ yóo sì dàbí afẹ́fẹ́ líle?
3
Ṣé Ọlọrun a máa yí ìdájọ́ po? Ṣé Olodumare a máa yí òdodo pada?
4
Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ dẹ́ṣẹ̀ ni, ó ti jẹ wọ́n níyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
5
Ṣugbọn bí o bá wá Ọlọrun, tí o sì sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Olodumare;
6
tí o bá jẹ́ ẹni mímọ́ ati olóòótọ́, dájúdájú OLUWA yóo dìde, yóo ràn ọ́ lọ́wọ́, yóo sì fi ibùgbé rere san ẹ̀san fún ọ.
7
Díẹ̀ ni ọrọ̀ tí o ní tẹ́lẹ̀ yóo jẹ́ lára ohun tí Ọlọrun yóo fún ọ ní ọjọ́ iwájú.
8
“Mo bẹ̀ ọ́, lọ wádìí nípa ìgbà àtijọ́, kí o ṣe akiyesi ìrírí àwọn baba wa.
9
Nítorí ọmọde ni wá, a kò mọ nǹkankan, ọjọ́ ayé wa sì dàbí òjìji.
10
Àwọn ni wọn óo kọ́ ọ, tí wọn óo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọn óo sì fún ọ ní ìmọ̀ràn ninu òye wọn.
11
“Ṣé koríko etídò le hù níbi tí kò sí àbàtà? Tabi kí èèsún hù níbi tí kò sí omi?
12
Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà tí ó bá ń tanná lọ́wọ́, yóo rọ ṣáájú gbogbo ewéko, láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni gé e lulẹ̀
13
Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbàgbé Ọlọrun rí; ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọrun yóo parun.
14
Igbẹkẹle rẹ̀ já sí asán, ìmúlẹ̀mófo ni, bí òwú aláǹtakùn.
15
Ó farati ilé rẹ̀, ṣugbọn kò le gbà á dúró. Ó dì í mú, ṣugbọn kò lè mú un dúró.
16
Kí oòrùn tó yọ, ẹni ibi a máa tutù yọ̀yọ̀, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ a sì gbilẹ̀ káàkiri inú ọgbà rẹ̀.
17
Ṣugbọn ara òkúta ni gbòǹgbò rẹ̀ rọ̀ mọ́, òun gan-an sì ń gbé ààrin àpáta.
18
Bí wọ́n bá fà á tu kúrò ní ààyè rẹ̀, kò sí ẹni tí yóo mọ̀ pé ó wà níbẹ̀ rí.
19
Ayọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ kò jù báyìí lọ, àwọn mìíràn óo dìde, wọn yóo sì gba ipò rẹ̀.
20
“Ṣugbọn Ọlọrun kò jẹ́ fi àwọn olóòótọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ ran ẹni ibi lọ́wọ́.
21
Yóo tún fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, ẹnu rẹ yóo kún fún ìhó ayọ̀.
22
Ojú yóo ti àwọn ọ̀tá rẹ, ilé àwọn eniyan burúkú yóo sì parẹ́.”
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42