bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 20
Job 20
Yoruba 2010
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 21 →
1
Sofari, ará Naama bá dáhùn pé,
2
“Lọ́kàn mi, mo fẹ́ fèsì sí ọ̀rọ̀ rẹ, ara sì ń wá mi, bí ẹni pé kí n dá ọ lóhùn.
3
Mo gbọ́ èébú tí o bú mi, mo sì mọ irú èsì tí ó yẹ kí n fọ̀.
4
Ṣé o kò mọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí wọ́n ti dá eniyan sórí ilẹ̀ ayé,
5
pé bí inú eniyan burúkú bá ń dùn, tí ẹni tí kò mọ Ọlọrun bá ń yọ̀, fún ìgbà díẹ̀ ni.
6
Bí ìgbéraga rẹ̀ tilẹ̀ ga, tí ó kan ọ̀run, tí orí rẹ̀ kan sánmà,
7
yóo ṣòfò títí lae bí ìgbọ̀nsẹ̀ ara rẹ̀, àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n yóo bèèrè pé, ‘Níbo ló wà?’
8
Yóo parẹ́ bí àlá, yóo sì di àwátì, yóo pòórá bí ìran tí a rí lóru.
9
Ojú tí ó ti ń rí i tẹ́lẹ̀ kò ní rí i mọ́, ààyè rẹ̀ yóo sì ṣófo.
10
Àwọn ọmọ rẹ̀ yóo máa wá ojurere àwọn aláìní, wọn yóo sì san ohun tí baba wọn gbà lọ́wọ́ aláìní pada.
11
Bí ó tilẹ̀ dàbí ọ̀dọ́, tí ó lágbára, sibẹ yóo lọ sí ibojì, yóo sì di erùpẹ̀.
12
Bí ọ̀rọ̀ ìkà tilẹ̀ dùn ní ẹnu rẹ̀, tí ó sì fi pamọ́ sí abẹ́ ahọ́n rẹ̀,
13
bí ó tilẹ̀ lọ́ra láti sọ ọ́ jáde, tí ó pa ẹnu mọ́,
14
sibẹsibẹ oúnjẹ rẹ̀ a máa dà á ninu rú, ó sì ti dàbí oró ejò paramọ́lẹ̀ ninu rẹ̀.
15
Gbogbo owó tí ó kó jẹ ni ó tún ń pọ̀ jáde; Ọlọrun ní ń pọ̀ wọ́n jáde ninu ikùn rẹ̀.
16
Yóo mu oró ejò, ahọ́n paramọ́lẹ̀ yóo pa á.
17
Kò ní gbádùn oyin ati wàrà tí ń ṣàn bí odò.
18
Kò ní jẹ èrè wahala rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ní gbádùn èrè tí ó bá jẹ nídìí òwò rẹ̀.
19
Nítorí pé ó ti tẹ aláìní mọ́lẹ̀, ó sì ti pa wọ́n tì sí apákan ó sì fi ipá gba ilé tí kò kọ́.
20
Nítorí pé oníwọ̀ra ni, tí ọkàn rẹ̀ bá nàró sí nǹkankan, kò lè pa á mọ́ra.
21
Kì í jẹ àjẹṣẹ́kù, nítorí náà, ọlá rẹ̀ kò le tọ́jọ́.
22
Ninu ọlá ńlá rẹ̀ yóo wà ninu àhámọ́, ìbànújẹ́ yóo máa fi tagbára-tagbára bá a jà.
23
Dípò kí ó jẹun ní àjẹyó, ibinu ńlá ni Ọlọrun yóo rán sí i, tí yóo sì dà lé e lórí.
24
Bí ó bá ti ń sá fún idà, bẹ́ẹ̀ ni ọfà bàbà yóo gún un ní àgúnyọ-lódì-keji.
25
Bí ó bá fa ọfà jáde kúrò lára rẹ̀, tí ṣóńṣó orí ọfà jáde láti inú òróòro rẹ̀, ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá a.
26
Òkùnkùn biribiri ń dúró dè é, iná tí eniyan kò dá ni yóo jó o ní àjórun, ohun ìní tí ó kù ní ibùgbé rẹ̀ yóo sì parun.
27
Ọ̀run yóo fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn, ilẹ̀ yóo dojú ìjà kọ ọ́.
28
Ibinu Ọlọrun gba àwọn ohun ìní rẹ̀ lọ, àgbàrá ibinu yóo gbá wọn dànù.
29
Bẹ́ẹ̀ ni ìpín ẹni ibi yóo rí. Ọlọrun ni ó ti yàn án bẹ́ẹ̀ láti ilẹ̀ wá.”
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 21 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42