bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 21
Job 21
Yoruba 2010
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 22 →
1
Jobu dáhùn pé,
2
“Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi dáradára, kí ẹ sì jẹ́ kí ó jẹ́ ìtùnú fun yín.
3
Ẹ farabalẹ̀, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, lẹ́yìn náà, ẹ lè máa fi mí ṣẹ̀sín ǹṣó.
4
Ṣé eniyan ni mò ń bá rojọ́ ni? Kí ló dé tí n óo fi mú sùúrù?
5
Ẹ wò mí, kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì fọwọ́ bo ẹnu.
6
Nígbà tí mo ro ohun tí ó dé bá mi, ẹ̀rù bà mí, mo sì wárìrì.
7
Kí ló dé tí eniyan burúkú fi wà láàyè, tí ó di arúgbó, tí ó sì di alágbára?
8
Àwọn ọmọ wọn ati arọmọdọmọ wọn di eniyan pataki pataki lójú ayé wọn.
9
Kò sí ìfòyà ninu ilé wọn, bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò jẹ wọ́n níyà.
10
Àwọn mààlúù wọn ń gùn, wọ́n sì ń bímọ ní àbíyè.
11
Wọn a máa kó àwọn ọmọ wọn jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa ṣe àríyá.
12
Wọn a máa fi aro, ìlù, ati fèrè kọrin, wọn a sì máa yọ̀ sí ohùn dùùrù.
13
Wọn a máa gbé inú ọlá, wọn a sì máa kú ikú alaafia.
14
Wọ́n ń sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀! A kò fẹ́ mọ òfin rẹ.
15
Ta ni Olodumare, tí a óo fi máa sìn ín? Èrè wo ni ó wà níbẹ̀ fún wa bí à ń gbadura sí i?’
16
Wọ́n rò pé ìkáwọ́ wọn ni ọlà wọn wà, nítèmi n kò lè tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú.
17
“Ìgbà mélòó ni à ń pa fìtílà ẹni ibi? Ìgbà mélòó ni iṣẹ́ ibi wọn ń dà lé wọn lórí? Tabi tí Ọlọrun ṣe ìpín wọn ní ìrora ninu ibinu rẹ̀?
18
Ìgbà mélòó ni wọ́n dàbí àgékù koríko, tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri, tabi bí ìyàngbò tí ìjì ń gbé lọ?
19
“O ní, ‘Ọlọrun ń to àìdára wọn jọ de àwọn ọmọ wọn.’ Jẹ́ kí ó dà á lé wọn lórí, kí wọ́n baà lè mọ ohun tí wọ́n ṣe.
20
Jẹ́ kí wọ́n fi ojú ara wọn rí ìparun ara wọn, kí wọ́n sì rí ibinu Olodumare.
21
Kí ni ó kàn wọ́n pẹlu ilé wọn mọ́, lẹ́yìn tí wọn bá ti kú, nígbà tí a bá ti ké ọjọ́ wọn kúrò lórí ilẹ̀.
22
Ṣé ẹnìkan lè kọ́ Ọlọrun ní ìmọ̀, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni onídàájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní ibi gíga?
23
Ẹnìkan kú ninu ọpọlọpọ ọrọ̀, nítorí pé ó wà ninu ìdẹ̀ra ati àìfòyà,
24
ara rẹ̀ ń dán fún sísanra, ara sì tù ú dé mùdùnmúdùn.
25
Ẹlòmíràn kú pẹlu ìbànújẹ́ ọkàn, láìtọ́ ohun rere kankan wò rí.
26
Bákan náà ni gbogbo wọn ṣe sùn ninu erùpẹ̀, tí ìdin sì bò wọ́n.
27
“Wò ó! Mo mọ èrò ọkàn yín, mo sì mọ ète tí ẹ ní sí mi láti ṣe mí níbi.
28
Nítorí ẹ wí pé, ‘Níbo ni ilé àwọn eniyan ńlá wà; níbo sì ni àgọ́ àwọn aṣebi wà?’
29
Ṣé ẹ kò tíì bèèrè ọ̀nà lọ́wọ́ àwọn arìnrìnàjò? Ṣé ẹ kò sì tíì gba ẹ̀rí wọn, pé,
30
a dá ẹni ibi sí ní ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀, ati pé a gbà á là ní ọjọ́ ibinu?
31
Kò sẹ́ni tó jẹ́ fẹ̀sùn kan ẹni ibi lójú rẹ̀, tabi kí ó gbẹ̀san nǹkan burúkú tí ó ṣe.
32
Nígbà tí a bá gbé e lọ sí itẹ́, àwọn olùṣọ́ a máa ṣọ́ ibojì rẹ̀.
33
Ẹgbẹẹgbẹrun èrò a tẹ̀lé e lọ sí ibojì, àìmọye eniyan a sì sin òkú rẹ̀; kódà, ilẹ̀ á dẹ̀ fún un ní ibojì rẹ̀.
34
Nítorí náà, kí ni ìsọkúsọ tí ẹ lè fi tù mí ninu? Kò sóhun tó kù ninu ọ̀rọ̀ yín, tó ju irọ́ lọ.”
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 22 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42