bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 37
Job 37
Yoruba 2010
← Chapter 36
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 38 →
1
“Nígbà tí mo gbọ́, ọkàn mi wárìrì, ó sì fò sókè ní ipò rẹ̀.
2
Gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ń dún bí ààrá, ati ariwo tí ń ti ẹnu rẹ̀ jáde.
3
Ó rán mànàmáná rẹ̀ sí wọn jákèjádò ojú ọ̀run, títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
4
Lẹ́yìn náà, a gbọ́ ìró ohùn rẹ̀, ó sọ̀rọ̀ ninu ọlá ńlá rẹ̀, bí ìgbà tí ààrá bá sán, sibẹsibẹ kò dá mànàmáná dúró bí àwọn eniyan ti ń gbóhùn rẹ̀.
5
Ohùn Ọlọrun dún bí ààrá tìyanu-tìyanu, a kò lè rí ìdí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
6
Ó pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni òjò wẹliwẹli, ati ọ̀wààrà òjò.
7
Ó ká gbogbo eniyan lọ́wọ́ iṣẹ́ kò, kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ rẹ̀.
8
Àwọn ẹranko wọ ihò wọn lọ, wọ́n dákẹ́ sibẹ, wọ́n sá pamọ́.
9
Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀, òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́.
10
Yìnyín ti inú èémí Ọlọrun wá, gbogbo omi inú odò sì dì.
11
Ó fi omi kún inú ìkùukùu, ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká.
12
Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀, láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè.
13
Ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀, bóyá fún àtúnṣe ni, tabi nítorí ilẹ̀ rẹ̀, tabi láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
14
“Fetí sílẹ̀, ìwọ Jobu, dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun.
15
Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun ṣe pàṣẹ, tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn?
16
Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ó ṣe so awọsanma rọ̀, iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ ni;
17
ìwọ tí ooru mú nígbà tí ayé dákẹ́ rọ́rọ́ nítorí pé afẹ́fẹ́ ìhà gúsù kò fẹ́?
18
Ṣé o lè tẹ́ ojú ọ̀run bí ó ti tẹ́ ẹ, kí ó le, kí ó sì dàbí dígí tí ń dán?
19
Kọ́ wa ní ohun tí a lè bá Ọlọrun sọ, a kò lè kó àròyé wa jọ siwaju rẹ̀, nítorí àìmọ̀kan wa.
20
Ṣé kí n sọ fún Ọlọrun pé n ó bá a sọ̀rọ̀ ni? Ta ni yóo fẹ́ kí á gbé òun mì?
21
“Ẹnikẹ́ni kò lè wo ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run nígbà tí ó bá ń tàn ní awọsanma, nígbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ tí ó sì gbá wọn lọ.
22
Láti ìhà àríwá ni Ọlọrun ti yọ, ó fi ọlá ńlá, tí ó bani lẹ́rù, bora bí aṣọ.
23
Àwámárìídìí ni Olodumare— agbára ati ìdájọ́ òtítọ́ rẹ̀ pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í kọ òdodo sílẹ̀.
24
Nítorí náà, gbogbo eniyan bẹ̀rù rẹ̀, kò sì náání àwọn tí wọ́n gbọ́n lójú ara wọn.”
← Chapter 36
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 38 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42