bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 4
Job 4
Yoruba 2010
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 5 →
1
Nígbà náà ni Elifasi, ará Temani, dá Jobu lóhùn, ó ní:
2
“Bí eniyan bá bá ọ sọ̀rọ̀, ṣé kò ní bí ọ ninu? Àbí eniyan ha lè dákẹ́ bí?
3
O ti kọ́ ọpọlọpọ eniyan, o ti fún aláìlera lókun.
4
O ti fi ọ̀rọ̀ gbé àwọn tí wọn ń ṣubú ró, ọ̀rọ̀ rẹ ti fún orúnkún tí ń yẹ̀ lọ lágbára.
5
Ṣugbọn nisinsinyii tí ọ̀rọ̀ kàn ọ́, o kò ní sùúrù; Ó dé bá ọ, ìdààmú bá ọ.
6
Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ? Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí?
7
“Ìwọ náà ronú wò, ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí? Tabi olódodo kan parun rí?
8
Bí èmi ti rí i sí ni pé, ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè, tí ó sì gbin wahala, yóo kórè ìyọnu.
9
Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run, ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé.
10
Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun, ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù, ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín.
11
Kinniun alágbára a máa kú, nítorí àìrí ẹran pa jẹ, àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká.
12
“Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létí mo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀.
13
Ninu ìran lóru, nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn,
14
ìbẹ̀rùbojo mú mi, gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.
15
Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi, gbogbo irun ara mi sì dìde.
16
Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí. Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró; gbogbo nǹkan parọ́rọ́, nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé,
17
‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀?
18
Nígbà tí ó jẹ́ pé, Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn iranṣẹ rẹ̀, a sì máa bá àṣìṣe lọ́wọ́ àwọn angẹli rẹ̀;
19
mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ, tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀, tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn.
20
Eniyan lè wà láàyè ní òwúrọ̀ kí ó kú kí ó tó di ọjọ́ alẹ́, wọn a parun títí lae láìsí ẹni tí yóo bìkítà.
21
Bí a bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fẹ̀mí tẹ̀, ṣé wọn kò ní kú bí aláìgbọ́n?’
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42