bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 9
Job 9
Yoruba 2010
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 10 →
1
Jobu dáhùn pé:
2
“Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí, ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?
3
Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn, olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè.
4
Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀, agbára rẹ̀ sì pọ̀. Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ?
5
Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀; tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú.
6
Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì.
7
Ó pàṣẹ fún oòrùn, oòrùn kò sì yọ; ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé;
8
òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ, tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀.
9
Ó dá àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run: Beari, Orioni, ati Pileiadesi ati àwọn ìràwọ̀ ìhà gúsù.
10
Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà.
11
Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i, ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀.
12
Wò ó! Ó já àwọn ohun tí ó wù ú gbà, ta ló lè dá a dúró? Ta ló tó bi í pé, ‘Kí ni ò ń ṣe?’
13
“Ọlọrun kò ní dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró, yóo fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn olùrànlọ́wọ́ Rahabu mọ́lẹ̀.
14
Báwo ni mo ṣe lè bá a rojọ́? Kí ni kí n sọ?
15
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn. Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú, lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí.
16
Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́, tí ó sì dá mi lóhùn, sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi.
17
Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀, ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí;
18
kò ní jẹ́ kí n mí, ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi.
19
Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni, agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ! Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́, ta ló lè pè é lẹ́jọ́?
20
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ ọ̀rọ̀ ẹnu mi yóo di ẹ̀bi rù mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́ṣẹ̀, sibẹsibẹ yóo fihàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.
21
N kò lẹ́bi, sibẹ n kò ka ara mi kún, ayé sú mi.
22
Kò sí ìyàtọ̀ lójú rẹ̀, nítorí náà ni mo fi wí pé, ati ẹlẹ́bi ati aláìlẹ́bi ni ó ti parun.
23
Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀, tí ó já sí ikú òjijì, a máa fi aláìṣẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà ninu ìdààmú wọn.
24
A ti fi ayé lé àwọn ẹni ibi lọ́wọ́, ó ti di àwọn adájọ́ rẹ̀ lójú. Bí kì í bá ṣe òun Ọlọrun, ta ló tún tó bẹ́ẹ̀?
25
“Ọjọ́ ayé mi ń sáré lọ tete, kò sí ẹyọ ọjọ́ kan tí ó dára ninu wọn.
26
Wọ́n sáré kọjá lọ bíi koríko ojú omi, bí ẹyẹ idì tí ń fò fẹ̀ẹ̀ lọ bá ohun tí ó fẹ́ pa.
27
Bí mo bá sọ pé kí n gbàgbé ìráhùn mi, kí n sì tújúká; kí n má ronú mọ́;
28
ẹ̀rù ìrora mi á bẹ̀rẹ̀ sí bà mí, nítorí mo mọ̀ pé o kò ní gbà pé n kò dẹ́ṣẹ̀.
29
Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá mi lẹ́bi, kí ni mo tún ń ṣe wahala lásán fún?
30
Ọṣẹ yòówù tí mo lè fi wẹ̀, kódà kí n fi omi yìnyín fọ ọwọ́,
31
sibẹ o óo tì mí sinu kòtò ìdọ̀tí. Kódà n óo di ohun ìríra sí aṣọ ara mi.
32
Ọlọrun kì í ṣe eniyan bíì mi, tí mo fi lè fún un lésì, tí a fi lè jọ rojọ́ ní ilé ẹjọ́.
33
Kò sí ẹnìkẹta láàrin àwa mejeeji, tí ó lè dá wa lẹ́kun.
34
Kí ó sọ pàṣán rẹ̀ sílẹ̀, kí ó má nà mí mọ́! Kí ìbẹ̀rù rẹ̀ má sì pá mi láyà mọ́!
35
Kí n baà le sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù, nítorí mo mọ inú ara mi.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42