bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 3
Job 3
Yoruba 2010
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 4 →
1
Nígbà tí ó yá, Jobu bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó fi ọjọ́ ìbí ara rẹ̀ bú.
2
Ó ní:
3
“Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi, ati alẹ́ tí wọ́n lóyún mi.
4
Jẹ́ kí ọjọ́ náà ṣókùnkùn biribiri! Kí Ọlọrun má ṣe ka ọjọ́ náà sí, kí ìmọ́lẹ̀ má ṣe tàn sí i mọ́.
5
Ṣe é ní ọjọ́ ìṣúdudu, ati òkùnkùn biribiri. Kí ìkùukùu ṣíji bò ó, kí òkùnkùn sì dẹ́rù bà á.
6
Kí òkùnkùn ṣú bo alẹ́ ọjọ́ náà biribiri, kí á yọ ọ́ kúrò ninu àwọn ọjọ́ tí ó wà ninu ọdún, kí á má sì ṣe kà á kún àwọn ọjọ́ tí wọ́n wà ninu oṣù.
7
Kí alẹ́ ọjọ́ náà di òfo, kí á má ṣe gbọ́ ìró ayọ̀ ninu rẹ̀ mọ́.
8
Kí àwọn tí wọ́n ń fi ọjọ́ gégùn-ún fi gégùn-ún, àní àwọn tí wọ́n lè fi àṣẹ rú Lefiatani sókè.
9
Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ rẹ̀ ṣókùnkùn, kí ìrètí rẹ̀ fún ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ já sí òfo, kí ó má rí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ mọ́;
10
nítorí pé kò sé inú ìyá mi nígbà tí ó fẹ́ bí mi, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mú ibi kúrò lọ́nà mi.
11
“Kí ló dé tí n kò kú nígbà tí ìyá mi ń rọbí lọ́wọ́, tí ó fẹ́ bí mi, tabi kí n kú, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n bí mi?
12
Kí ló dé tí ìyá mi gbé mi lẹ́sẹ̀? Kí ló dé tí ó fi fún mi lọ́mú?
13
Ǹ bá ti dùbúlẹ̀, ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́; ǹ bá ti sùn, ǹ bá sì ti máa sinmi
14
pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìgbìmọ̀ àgbáyé, tí wọ́n ti sùn, àwọn tí wọ́n tún àlàpà kọ́ fún ara wọn;
15
tabi pẹlu àwọn ọmọ aládé tí wọ́n ní wúrà, tí fadaka sì kún ilé wọn.
16
Tabi kí n rí bí ọmọ tí a bí ní ọjọ́ àìpé, tí a bò mọ́lẹ̀ láì tíì lajú sáyé.
17
Níbi tí àwọn oníṣẹ́ ibi kò ti lágbára mọ́, tí àwọn tí gbogbo nǹkan ti sú gbé ń sinmi.
18
Níbẹ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń gbé pọ̀ pẹlu ìrọ̀rùn, wọn kò sì gbọ́ ohùn akóniṣiṣẹ́ mọ́.
19
Àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki jọ wà níbẹ̀, àwọn ẹrú sì bọ́ lọ́wọ́ oluwa wọn.
20
“Kí ló dé tí a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ń kérora, tí a fi ẹ̀mí fún ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́;
21
tí ó ń wá ikú, ṣugbọn tí kò rí; tí ó ń wá ikú lójú mejeeji ju ẹni tí ń wá ìṣúra tí a fi pamọ́ lọ?
22
Àwọn tí inú wọn ìbá dùn lọpọlọpọ bí wọ́n bá rí ẹni gbé wọn sin.
23
Kí ló dé tí a fi fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà dàrú mọ́ lójú; ẹni tí Ọlọrun ti tì sinu àhámọ́?
24
Nítorí ìmí ẹ̀dùn di oúnjẹ fún mi, ìráhùn mi sì ń tú jáde bí omi.
25
Ohun tí mo bẹ̀rù jù ti dé bá mi, ohun tí ń fò mí láyà ti ṣẹlẹ̀ sí mi.
26
N kò ní alaafia, bẹ́ẹ̀ ni ara kò rọ̀ mí, n kò sì ní ìsinmi, àfi ìyọnu.”
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42