bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Job 29
Job 29
Yoruba 2010
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 30 →
1
Jobu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé,
2
“Ìbá jẹ́ tún rí fún mi, bí ìgbà àtijọ́, nígbà tí Ọlọrun ń tọ́jú mi;
3
nígbà tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn sí mi lórí, tí mo kọjá ninu òkùnkùn pẹlu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀;
4
kí ó tún rí fún mi bí ìgbà tí ara dẹ̀ mí, nígbà tí ìrẹ́pọ̀ wà láàrin Ọlọrun ati ìdílé mi;
5
tí Olodumare wà pẹlu mi, tí gbogbo àwọn ọmọ mi yí mi ká;
6
tí mò ń rí ọpọlọpọ wàrà lára àwọn ẹran ọ̀sìn mi, ati ọpọlọpọ òróró lára igi olifi tí ń dàgbà láàrin òkúta!
7
Nígbà tí mo lọ sí ẹnubodè ìlú, tí mo jókòó ní gbàgede,
8
tí àwọn ọdọmọkunrin bá rí mi, wọn á bìlà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, àwọn àgbà á sì dìde dúró;
9
àwọn ìjòyè á dákẹ́ rọ́rọ́, wọn á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn.
10
Àwọn olórí á panumọ́, ahọ́n wọn á lẹ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.
11
Àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa mi, ń pè mí ní ẹni ibukun, àwọn tí wọ́n rí mi ń kan sáárá sí mi.
12
Nítorí pé mò ń ran àwọn aláìní tí ń ké lọ́wọ́, ati àwọn aláìníbaba tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́.
13
Ìre àwọn tí ń kú lọ mọ́ mi, mo sì mú kí opó kọrin ayọ̀.
14
Mo fi òdodo bora bí aṣọ, ìdájọ́ òtítọ́ dàbí ẹ̀wù ati adé mi.
15
Mo jẹ́ ojú fún afọ́jú, ati ẹsẹ̀ fún arọ.
16
Mo jẹ́ baba fún talaka, mo gba ẹjọ́ àlejò rò.
17
Mo ṣẹ́ ẹni ibi lápá, mo gba ẹni tí ó mú sílẹ̀.
18
“Nígbà náà, mo rò pé, n óo gbòó, n óo tọ̀ọ́ láyé, ati pé inú ilé mi ni n óo sì kú sí.
19
Mo ta gbòǹgbò lọ síbi omi, ìrì sì ń sẹ̀ sí ẹ̀ka mi ní alaalẹ́.
20
Ọlá hàn lára mi, agbára mi sì ń di titun nígbà gbogbo.
21
Àwọn eniyan á dákẹ́ jẹ́ẹ́, wọn á farabalẹ̀ gbọ́ tèmi, wọ́n sì ń gba ìmọ̀ràn mi pẹlu.
22
Lẹ́yìn tí mo bá ti sọ̀rọ̀ tán, ẹnikẹ́ni kì í tún sọ̀rọ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ mi a máa wọ̀ wọ́n lára.
23
Wọ́n ń retí mi, bí ẹni retí òjò àkọ́rọ̀.
24
Mo rẹ́rìn-ín sí wọn nígbà tí wọn ń ṣiyèméjì, wọn kò sì lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi.
25
Mo jókòó bí ọba, mò ń tọ́ wọn sọ́nà, mo dàbí ọba láàrin àwọn ọmọ ogun rẹ̀, bí olùtùnú fún oníròbìnújẹ́.
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 30 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42