bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 1
Proverbs 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 2 →
1
Àwọn òwe ti Sólómónì, ọmọ Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì.
2
Láti le ní ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́ Láti ní òye àwọn ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀
3
Láti ní ẹ̀kọ́ àti gbé ìgbé ayé ìkíyèsára, láti ṣe ohun tí ó tọ́, àti òdodo tí ó sì dára
4
láti fún onírẹ̀lẹ̀ ní ìkíyèsára ìmọ̀ àti ìṣọ́ra fún àwọn èwe
5
Jẹ́ kí Ọlọgbọ́n tẹ́tí kí ó sì ní ìmọ̀ kún ìmọ̀, sì jẹ́ kí ẹni òye gba ìtọ́sọ́nà
6
láti mọ ìtumọ̀ òwe àti ìtàn-dòwe, (àlọ́ onítàn) àwọn ọ̀rọ̀ àti àlọ́ àwọn Ọlọgbọ́n.
7
Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.
8
Tẹ́tí, ìwọ ọmọ mi sí ẹ̀kọ́ baba rẹ má ṣe kọ ẹ̀kọ́ màmá ọ̀ rẹ sílẹ̀
9
Wọn yóò jẹ́ òdòdó ẹ̀yẹ olóòrùn dídùn lórí rẹ àti ọ̀ṣọ́ tí ó dára yí ọrùn rẹ ká.
10
Ọmọ mi, bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń tàn ọ́, má ṣe gbà fún wọn.
11
Bí wọn bá wí pé, “Tẹ̀lé wa kálọ; jẹ́ ká ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ ká dá àwọn aláìlera kan lọ́nà;
12
Jẹ́ ká gbé wọn mì láàyè, bí ibojì òkú, àti lódindi, bí àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sínú kòtò;
13
A ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó níye lórí a ó sì fi ìkógún kún inú ilé wa;
14
Dara pọ̀ mọ́ wa, a ó sì jọ powó sínú àpò kan náà”
15
Ọmọ mi, má ṣe bá wọn lọ, má ṣe rìn ní ojú ọ̀nà wọn;
16
Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.
17
Wàhálà asán ni kí ènìyàn máa dẹ okùn de ẹyẹ, ní ìṣojú u gbó ẹyẹ!
18
Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń lúgọ fún ẹ̀jẹ̀ ara wọn. Ara wọn ni wọ́n ń dá lóhùn
19
Báyìí ni ìgbẹ̀yìn gbogbo àwọn tí ń wá èrè àìtọ́; yóò mú ẹ̀mí gbogbo ẹni tí ó rí i lọ Ìkìlọ̀ láti má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀
20
Ọgbọ́n kígbe sókè ní pópó ó gbé ohùn rẹ̀ sókè láàrin ọjà;
21
Láàrin ọjà ni ó ti kígbe jáde Ní ibodè ìlú ni ó ti sọ̀rọ̀ ọ rẹ̀:
22
“Yóò ha ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin aláìmọ́kan yóò fi fẹ́ àìmọ̀kan yín tó? Yóò ha ti pẹ́ tó tí àwọn ẹlẹ́gàn yóò ṣe inú dídùn sí ìpẹ̀gàn tó? Àwọn aláìgbọ́n kórìíra ìmọ̀?
23
Bí ẹ bá ti gbọ́ ìbáwí ì mi ni, Ǹ bá ti tú ohun tí ó wà nínú ọkàn mi jáde fún yín kí n sì fi inú un mi hàn sí i yín.
24
Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ ti kọ ìpè ní ìgbà tí mo pè kò sì sí ẹni tí ó kọ ibi ara sí mi gbà tí mo háwọ́ sí wọn,
25
Níwọ̀n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi tí ẹ kò sì ní gba ìbáwí mi
26
Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín N ó sẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín
27
Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle, Nígbà tí ìdàámú bá dé bá ọ bí ààjà, nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.
28
“Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn; wọn yóò farabalẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi.
29
Níwọ̀n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀ tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù OLÚWA.
30
Níwọ̀n bí wọn kò ti gbà ìmọ̀ràn mi tí wọ́n sì kẹ́gàn ìmọ̀ràn mi,
31
Wọn yóò jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn wọn yóò sì jèrè èso ètè wọn ní kíkún
32
Nítorí ìrìnkurìn àwọn aláìmọ́kan ni yóò pa wọ́n ìkáwọ́-gbera aláìgbọ́n ni yóò pa á run;
33
Ṣùgbọ́n ẹnìkan tí ó bá fetí sí mi, yóò gbé láìléwu yóò sì wà nínú ìdẹ̀ra, láì sí ìbẹ̀rù ìpalára.”
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31