bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 12
Proverbs 12
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 13 →
1
Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.
2
Ènìyàn rere gba ojú rere lọ́dọ̀ OLÚWA ṣùgbọ́n OLÚWA kórìíra alárekérekè ènìyàn.
3
A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú ṣùgbọ́n a kò le è fa Olódodo tu.
4
Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí ìgbà tí inú egungun rẹ̀ jẹrà.
5
Ète àwọn Olódodo dára ṣùgbọ́n ìmúra ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.
6
Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀ ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn Olódodo gbà wọ́n là.
7
A sí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́; ṣùgbọ́n ilé Olódodo dúró ṣinṣin.
8
A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.
9
Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́ ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láì lóúnjẹ.
10
Ènìyàn rere ń ṣaájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò Àmọ́ ìwà tó dára jù tí ènìyàn búburú lè hù, ibi ni.
11
Ẹni tí ó bá dáko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásánlàsàn kò gbọ́n.
12
Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógún àwọn ènìyàn ìkà ṣùgbọ́n gbòǹgbò Olódodo ń gbilẹ̀.
13
A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n Olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdàámú.
14
Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.
15
Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n Ọlọgbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.
16
Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.
17
Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí tòótọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.
18
Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọgbọ́n ń mú ìwòsàn wá.
19
Ètè tí ń sòótọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.
20
Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú ṣùgbọ̀n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.
21
Ibi kì í ṣubú lu Olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.
22
OLÚWA kóìríra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn Olóòótọ́.
23
Ènìyàn Olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.
24
Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jọba ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí sínsìnrú.
25
Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
26
Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn sìnà.
27
Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.
28
Ní ọ̀nà àwọn Olódodo ni ìyè wà ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31