bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 20
Proverbs 20
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 21 →
1
Ẹlẹ́yà ni ọtí wáìnì, aláriwo sì ní ọ̀tí líle ẹnikẹ́ni tí ó bá sìnà nìpaṣẹ̀ wọn kò gbọ́n.
2
Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún; ẹnikẹ́ni tí ó bá mú-un bínú ba ayé ara rẹ̀ jẹ́.
3
Iyì ni ó jẹ́ fún ènìyàn láti sá fún ìjà ṣùgbọ́n gbogbo aláìgbọ́n a máa tètè wá ìjà.
4
Ọ̀lẹ kì í ṣiṣẹ́ oko nígbà tí ó yẹ nítorí náà ní àsìkò ìkórè, yóò wá kò sì ní rì nǹkan.
5
Ètè ọkàn ènìyàn dàbí, omi jínjìn; ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.
6
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n máa ń wí oore wọn jáde, ṣùgbọ́nn kò rọrùn láti rí ènìyàn olóòótọ́.
7
Olódodo ènìyàn a máa gbé ìgbé ayé àìlábùkù ìbùkún ni fún àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
8
Nígbà tí ọba bá jókóò sórí ilẹ̀ rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ yóò fẹ́ gbogbo ibi dànù pẹ̀lú ojú rẹ̀.
9
Táni ó le è wí pé, “Mo ti ṣe ọkàn mi ní mímọ́, mo mọ́, n kò sì lẹ́ṣẹ̀”?
10
Ìdíwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ OLÚWA kórìíra méjèèjì.
11
Kódà a mọ ọmọdé nípa iṣẹ́ rẹ̀ nípa pe bóyá iṣẹ́ rẹ mọ́ tàbí pé ó tọ̀nà.
12
Etí tí ó ń gbọ́ àti ojú tí ó ń ríran OLÚWA ni ó dá méjèèjì.
13
Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di talákà má ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ.
14
“Kò dára, kò dára” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán, yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí i rà sí.
15
Góòlù wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.
16
Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò; mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn.
17
Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà ẹ̀rú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn ṣùgbọ́n, a yọrí sí bi ẹnu tí ó kún fún èèpẹ̀.
18
Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn bí o bá ń jagun, gba ìtọ́ṣọ́nà.
19
Olófòófó dalẹ̀ àsírí nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ jù.
20
Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri.
21
Ogún tí a kó jọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín.
22
Má ṣe wí pé, “N ó ṣẹ̀ṣan àṣìṣe rẹ yìí fún ọ” Dúró de OLÚWA yóò sì gbà ọ́ là.
23
OLÚWA kórìíra òdiwọ̀n èké. Òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn.
24
OLÚWA ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni?
25
Ìdẹkùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò.
26
Ọlọgbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká; Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n.
27
Àtùpà OLÚWA ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú
28
Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́, nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu.
29
Ògo ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn jẹ́ ewú orí ni iyì arúgbó.
30
Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ, pàsán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 21 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31