bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 6
Proverbs 6
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 7 →
1
Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe oníduúró fún aládùúgbò rẹ bí ìwọ bá ti bọwọ́ ní ìlérí májẹ̀mu pẹ̀lú ẹlòmíràn
2
Bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté,
3
Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ níwọ̀n bí o ti kó sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ: lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀; bẹ aládùúgbò rẹ dáadáa
4
Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́, tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá.
5
Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo àgbọ̀nrín kúrò lọ́wọ́ ọdẹ, bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ.
6
Tọ èèrùn lọ, ìwọ ọ̀lẹ kíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n!
7
Kò ní olùdarí, kò sí alábojútó tàbí ọba,
8
síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè.
9
Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ? Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ?
10
Oorun díẹ̀, Òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀
11
Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà àti àìní bí adigunjalè.
12
Ènìyàn kénìyàn àti ènìyàn búburú, tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri,
13
tí ó ń sẹ́jú pàkòpàkò, ó ń fi ẹsẹ̀ ṣe àmì ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe,
14
tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀ ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀.
15
Nítorí náà ìdààmú yóò dé báa ní ìsẹ́jú akàn; yóò parun lójijì láì sí àtúnṣe.
16
Àwọn ohun mẹ́fà wà tí OLÚWA kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra síi:
17
Ojú ìgbéraga, Ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,
18
ọkàn tí ń pète ohun búburú, ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà,
19
Ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ ìyá kan.
20
Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́ má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
21
Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ
22
Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ; nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùsọ́ rẹ; nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀.
23
Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ àtùpà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́niṣọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè
24
yóò pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin oníṣekúṣe kúrò lọ́wọ́ ẹnu dídùn aya tí ń rin ìrìnkurìn
25
Má ṣe ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ síi nínú ọkàn rẹ nítorí ẹwà rẹ tàbí kí o jẹ́ kí ó fi ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra,
26
nítorí Aṣẹ́wó yóò sọ ọ́ di àkàrà lásánlàsàn ẹ̀mí rẹ gan an sì ni alágbérè ń dọdẹ.
27
Ǹjẹ́ ènìyàn ha le è gbé iná lé orí itan kí aṣọ rẹ̀ sì má jòó?
28
Ǹjẹ́ ènìyàn le è máa rìn lórí iná? Kí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì má jóná?
29
Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sùn pẹ̀lú aya aláya; kò sí ẹni tí ó fọwọ́ kàn án tí yóò lọ láì jìyà.
30
Àwọn ènìyàn kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jalè nítorí àti jẹun nígbà tí ebi bá ń pa á.
31
Ṣíbẹ̀ bí ọwọ́ bá tẹ̀ẹ́, ó gbọdọ̀ san ìlọ́po méje bí ó tilẹ̀ kó gbogbo ohun tó ní nílé tà.
32
Ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbérè kò nírònú; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ó ń pa ara rẹ̀ run ni
33
Ìfarapa àti ìtìjú ni tirẹ̀, ẹ̀gàn rẹ̀ kì yóò sì kúrò láéláé;
34
nítorí owú yóò ru ìbínú ọkọ sókè, kì yóò sì ṣàánú nígbà tí ó bá ń gbẹ̀san.
35
Kò ní gba nǹkankan bí ohun ìtanràn; yóò kọ àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kí ó pọ̀ tó.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31