bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 7
Proverbs 7
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 8 →
1
Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.
2
Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ
3
Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun kọ wọ́n sí inú ọkàn rẹ.
4
Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,” sì pe òye ní ìbátan rẹ;
5
wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè, kúrò lọ́wọ́ ìyàwó onírìnkurìn àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.
6
Ní ojú fèrèsé ilé è mi mo wo ìta láti ojú ù fèrèsé.
7
Mo rí i láàrin àwọn aláìmọ́kan mo sì kíyèsí láàrin àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.
8
Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbérè obìnrin náà, ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀
9
ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣẹ ń bo ni lára.
10
Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀, ó múra bí aṣẹ́wó pẹ̀lú ètè búburú.
11
(Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí, ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;
12
bí ó ti ń já níhìn ín ní ó ń já lọ́hùn ún gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)
13
Ó dìí mú, ó sì fẹnu kò ó ní ẹnu pẹ̀lú ojú dídín ó wí pé:
14
“Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé; lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.
15
Nítorí náà ni mo ṣe jáde wá pádé è rẹ; mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!
16
Mo ti tẹ́ ibùṣùn mi pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Éjíbítì.
17
Mo ti fi nǹkan Olóòórùn dídùn sí ibùṣùn mi bí i míra, álóè àti kínámónì.
18
Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀; jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!
19
Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé; ó ti lọ sí ìrìnàjò jínjìn.
20
Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”
21
Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.
22
Kíákíá ni ó tẹ̀lé e bí i màlúù tí ń lọ sí odò ẹran bí àgbọ̀nrín tí ó fẹ́ kẹsẹ̀ bọ pàkúté
23
títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, Láì mọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.
24
Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.
25
Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀, tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.
26
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀ Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.
27
Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààra sí iṣà òkú, tí ó lọ tààra sí àgbàlá ikú.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31