bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 18
Proverbs 18
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 19 →
1
Ènìyàn tí kò báni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀; ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.
2
Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye ṣùgbọn ó ní inú dídùn sí ṣíṣọ èrò tirẹ̀.
3
Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.
4
Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jínjìn ṣùgbọ́n oríṣun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń ṣàn.
5
Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúṣáájú fún ènìyàn búburú tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.
6
Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀ ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.
7
Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́ ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹkùn fún ọkàn rẹ̀.
8
Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn wọ́n ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí akínyẹmí ara.
9
Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀ arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.
10
Orúkọ OLÚWA, ilé ìṣọ́ agbára ni; olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.
11
Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.
12
Sáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
13
Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́ òun náà ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.
14
Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.
15
Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀; etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.
16
Ẹ̀bùn máa ń sí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.
17
Ẹni tí ó kọ́kọ́ rojọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àsírí gbogbo.
18
Ìbò dídì máa ń parí ìjà a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.
19
Arákùnrin tí a ṣẹ̀ ṣòroó yípadà ju ìlú olódi lọ, ìjà sì dàbí ibodè ìlú olódi ńlá tí a ṣe.
20
Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó; láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.
21
Ahọ́n ni agbára ìyè àti ikú, àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹẹ́.
22
Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere, Ó sì gba ojú rere lọ́dọ̀ OLÚWA.
23
Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú, Ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.
24
Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun Ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó sún mọ́ ni tímọ́ tímọ́ ju arákùnrin.
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 19 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31