bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 17
Proverbs 17
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 18 →
1
Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́jẹ́ sàn ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.
2
Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ, yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.
3
Iná ni a fi fọ́ Sílífà àti wúrà Ṣùgbọ́n OLÚWA ló ń dán ọkàn wò.
4
Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.
5
Ẹni tí ó fi talákà ṣe yẹ̀yẹ́ kórìíra ẹlẹ́dàá talákà náà ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ torí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.
6
Ọmọ-Ọmọ ni adé orí arúgbó òbí sì ni ìyangàn àwọn ọmọ.
7
Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aláìgbọ́n, mélòó mélòó ni ètè tí ń parọ́ fún àwọn alákóso!
8
Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ oògùn fún ẹni tí ó ń fún ni ohun gbogbo, ibikíbi tí ó bá tẹ̀ sí ni ó ń yege.
9
Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì níyà.
10
Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun ènìyàn olóye ju ọgọ́rùn ún pàsán lẹ́yìn aláìgbọ́n.
11
Oríkunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe, ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i.
12
Ó sàn kí ènìyàn pàdé béárì tí a ti kó lọ́mọ jù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.
13
Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ire, ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé.
14
Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà.
15
Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, OLÚWA kóríra méjèèjì.
16
Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè níwọ̀n bí kò ti ní èròńgbà láti rí ọgbọ́n?
17
Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, Arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú.
18
Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀.
19
Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀; ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun.
20
Ènìyàn aláyìídáyidà ọkàn kì í gbèrú ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu.
21
Láti bí aláìgbọ́n lọmọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n.
22
Ọkàn tí ó túká jẹ́ ogún gidi ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ.
23
Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ láti yí ìdájọ́ po.
24
Olóyè ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé.
25
Aláìgbọ́n ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀ àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ.
26
Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀ tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn.
27
Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ ènìyàn olóye sì máa ń ní ṣùúrù.
28
Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọgbọ́n bí ó bá dákẹ́ àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 18 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31