bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 19
Proverbs 19
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 18
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 20 →
1
Ó sàn kí èèyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.
2
Kò dára láti ní ìtara láì ní ìmọ̀ tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì sìnà.
3
Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run; ṣíbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí OLÚWA.
4
Ọrọ̀ má a ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ̀n ọ̀rẹ́ ẹ talákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
5
Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láì jìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.
6
Ọ̀pọ̀ ń wá ojú rere Olórí; gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.
7
Gbogbo ará ilé e talákà ni ó pa á tì mélòómélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un! Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀, kò tilẹ̀ rí wọn rárá.
8
Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀; ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.
9
Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.
10
Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọlá ńlá, mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jọba lórí ọmọ aládé.
11
Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní ṣùúrù; fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.
12
Ìbínú ọba dàbí kíke e kìnnìún, ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.
13
Aláìgbọ́n ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀sọ̀ọ̀rọ̀ òjò.
14
A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí ṣùgbọ́n aya olóye láti ọdọ̀ OLÚWA ni.
15
Ọ̀lẹ ṣíṣẹ́ máa ń fa oorun sísùn fọnfọnfọn ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.
16
Ẹni-kẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.
17
Ẹni tí ó ṣáànú talákà, OLÚWA ní ó yá yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.
18
Bá ọmọ rẹ wí nítorí nínú ìyẹn ni ìrètí wà; àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ lọ́wọ́ nínú iparun un rẹ̀.
19
Ènìyàn onínú-fùfù gbọdọ̀ gba èrè ìwà rẹ̀ bí ìwọ bá gbàá là, ìwọ yóò tún ní láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan síi.
20
Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́ ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.
21
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ète inú ọkàn ènìyàn ṣùgbọ́n ìfẹ́ OLÚWA ní ó máa ń borí.
22
Ohun tí ènìyàn ń fẹ́ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀; ó sàn láti jẹ́ talákà ju òpùrọ́ lọ.
23
Ìbẹ̀rù OLÚWA ń mú ìyè wá: nígbà náà ọkàn ń balẹ̀, láì sí ewu.
24
Ọ̀lẹ ki ọwọ́ rẹ̀ bọ inú àwo oúnjẹ; kò tilẹ̀ ní mú u padà wá sí ẹnu rẹ̀.
25
Na ẹlẹ́gàn, òpè yóò sì kọ́gbọ́n; bá olóye ènìyàn wí, yóò sì ní ìmọ̀ síi.
26
Ẹni tí ó já baba rẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì lé ìyá rẹ̀ jáde ó jẹ́ adójútini ọmọ.
27
Yéé tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ tí í mú ni ṣìnà ọmọ mi, ìwọ kì yóò sì sìnà kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìmọ̀.
28
Ajẹ́rìí tí ó bàjẹ́ máa ń kẹ́gàn ìdájọ́ òtítọ́ ẹnu ènìyàn búburú sì ń gbé ibi mi.
29
A ti pèṣè ìjìyà sílẹ̀ fún ẹlẹ́gàn; àti pàṣán fún ẹ̀yìn aláìgbọ́n.
← Chapter 18
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 20 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31