bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 16
Proverbs 16
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 17 →
1
Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ OLÚWA ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.
2
Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dà bí i pé ó dára lójú ara rẹ̀ Ṣùgbọ́n OLÚWA ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.
3
Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé OLÚWA lọ́wọ́ Èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.
4
OLÚWA ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́ Kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.
5
OLÚWA kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀ mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.
6
Nípaṣẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀ nípaṣẹ̀ ìbẹ̀rù OLÚWA ènìyàn sá fún ibi.
7
Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ OLÚWA lọ́rùn, yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn-án bá a gbé ní àlàáfíà.
8
Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú.
9
Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀ ṣùgbọ́n OLÚWA ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.
10
Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa inú síi ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ gbé ẹ̀bi fún ara rẹ̀.
11
Òdiwọ̀n àti òṣùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA; gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.
12
Àwọn ọba kórìírà ìwà àìtọ́ nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.
13
Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣòótọ́ ènìyàn tí ń sọ òtítọ́ ṣe iyebíye sí wọn.
14
Ìrànṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.
15
Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè; ojú rere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.
16
Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà!
17
Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi, ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.
18
Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun, agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú,
19
ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrin àwọn olùpọ́njú jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.
20
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ire, ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé OLÚWA.
21
Àwọn tí ó gbọ́n nínú ọkàn là ń pè ní olóye ọ̀rọ̀ ìtura sì ń mú ẹ̀kọ́ gbèrú.
22
Òye jẹ́ oríṣun ìyè fún àwọn tí ó ní i, ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ ń kó ìyà jẹ aláìgbọ́n.
23
Ọkàn ọlọgbọ́n ènìyàn a máa ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ètè rẹ̀ sì ń mú kí ẹ̀kọ́ gbèrú.
24
Ọ̀rọ̀ ìtura dàbí afárá oyin ó dùn fún ọkàn, ó sì fi ìlera fún egungun.
25
Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.
26
Ìfẹ́-àti-jẹun alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún un nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ ni.
27
Ènìyàn búburú ń pète ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.
28
Aláyìídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀ olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn níyà.
29
Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.
30
Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte; ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.
31
Ewú orí jẹ́ ògo ìgbé ayé òdodo ní í múni débẹ̀.
32
Ó sàn láti jẹ́ oníṣùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun-gbàlú lọ.
33
A ṣẹ́ kèké dàsí ìṣẹ́po aṣọ, ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 17 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31