bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 3
Proverbs 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 4 →
1
Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ mi. Ṣùgbọ́n pa òfin mi mọ́ sí ọkàn rẹ.
2
Nítorí wọn yóò fún ọ ní ọjọ́ gígùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí ó sì mú ọ̀rọ̀ wá fún ọ.
3
Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àti òtítọ́ ṣíṣe fi ọ́ sílẹ̀ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ, kọ wọ́n sí síléètì àyà rẹ.
4
Nígbà náà ni ìwọ yóò rí ojú rere àti orúkọ rere ní ojú Ọlọ́run àti lójú ènìyàn.
5
Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ;
6
Jẹ́wọ́ rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ yóò sì ṣe àkóso ọ̀nà rẹ.
7
Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara à rẹ bẹ̀rù OLÚWA kí o sì kórìíra ibi.
8
Èyí yóò mú ìlera fún ara à rẹ àti okun fún àwọn egungun rẹ.
9
Fi ọrọ̀ rẹ bọ̀wọ̀ fún OLÚWA, pẹ̀lú àkọ́so oko ò rẹ
10
Nígbà náà ni àká rẹ yóò kún àkúnya àgbá rẹ yóò kún à kún wọ́ sílẹ̀ fún wáìnì tuntun.
11
Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí OLÚWA má si ṣe bínú nígbà tí ó bá ń bá ọ wí,
12
Nítorí OLÚWA a máa bá àwọn tí ó fẹ́ràn wí bí baba ti í bá ọmọ tí ó bá nínú dídùn sí wí.
13
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀, ẹni tí ó tún ní òye síi
14
Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
15
Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ; kò sí ohunkohun tí a lè fi wé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
16
Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; ní ọwọ́ òsì rẹ̀ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
17
Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìtura, òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
18
Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbàá; àwọn tí ó bá sì dìí mú yóò rí ìbùkún gbà.
19
Nípa ọgbọ́n, OLÚWA fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipòo wọn;
20
Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní ìyà, àwọ̀sánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.
21
Ọmọ mi pa ìdájọ́ tí ó yè kooro mọ́ àti ìmọ̀yàtọ̀, má jẹ́ kí wọn lọ kúrò ní ibi tí ojú rẹ ti le tó wọn
22
wọn yóò jẹ́ ìyè fún ọ àti ẹ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ
23
Nígbà náà ni ìwọ yóò bá ọ̀nà rẹ lọ ní àìṣéwu, ìwọ kì yóò sì kọsẹ̀;
24
Nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, ìwọ kì yóò bẹ̀rù nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, oorun rẹ yóò jẹ́ oorun ayọ̀
25
má ṣe bẹ̀rù ìdàámú òjijì tàbí ti ìparun tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn búburú
26
Nítorí OLÚWA yóò jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ kì yóò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ bọ́ sínú pàkúté.
27
Má ṣe fa ọwọ́ ire sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó tọ́ sí, nígbà tí ó bá wà ní ìkápá rẹ láti ṣe ohun kan.
28
Má ṣe wí fún aládùúgbò rẹ pé, “Padà wá nígbà tó ṣe díẹ̀; ó fún ọ lọ́lá” nígbà tí o ní i pẹ̀lú rẹ nísinsin yìí.
29
Má ṣe pète ohun búburú fún aládùúgbò rẹ, ti o gbé nítòsí rẹ, tí ó sì fọkàn tán ọ.
30
Má ṣe fẹ̀ṣùn kan ènìyàn láì-ní-ìdí nígbà tí kò ṣe ọ́ ní ibi kankan rárá.
31
Má ṣe ṣe ìlara ènìyàn jàgídíjàgan tàbí kí o yàn láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀,
32
Nítorí OLÚWA kórìíra ènìyàn aláyìídáyidà ṣùgbọ́n a máa fọkàn tán ẹni dídúró ṣinṣin.
33
Ègún OLÚWA ń bẹ lórí ilé ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó bùkún fún ilé olódodo
34
Ó fi àwọn oníyẹ̀yẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ Ṣùgbọ́n ó fi oore ọ̀fẹ́ fún onírẹ̀lẹ̀
35
ọlọ́gbọ́n jogún iyì Ṣùgbọ́n àwọn aláìgbọ́n ni ó dójú tì.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31