bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 8
Proverbs 8
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 9 →
1
Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta? Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
2
Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ní ìkòríta, ní ó dúró;
3
Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú, ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
4
Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè; Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,
5
Ẹ̀yin aláìmọ́kan, ẹ kọ́gbọ́n; ẹ̀yin aláìgbọ́n, ẹ gba òye.
6
Tẹ́tí, nítorí mo ní àwọn ohun iyebíye láti sọ; Mo ya ẹnu mi láti sọ àwọn ohun tí ó tọ̀nà,
7
Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́, nítorí ètè mi kórìíra ibi.
8
Gbogbo ọrọ ẹnu mi ni ó tọ́, kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyídà níbẹ̀
9
Fún Olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà; wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
10
Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà, ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
11
Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù ìyùn lọ, kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fi wé e.
12
“Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye; mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
13
Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìkóòríra ibi mo kóríra ìgbéraga àti agídí, ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
14
Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi mo ní òye àti agbára.
15
Nípaṣẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára
16
Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ aládé ń ṣàkóso àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17
Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18
Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà Ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19
Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20
Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21
mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
22
“Èmi ni OLÚWA kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
23
A ti yàn mí láti ayérayé, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
24
Nígbà tí kò tíì sí òkun, ni a ti bí mi nígbà tí kò tíì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
25
kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
26
kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
27
Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
28
Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfuurufú lókè tí ó sì fi oríṣun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹṣẹ̀,
29
Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi òkun kí omi má baà kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
30
Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ẹ rẹ̀ mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, mo ń yọ̀ nígbà gbobgbo níwájú rẹ̀
31
mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.
32
“Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́
33
fetí sí ìtọ́ṣọ́nà mi kí o sì gbọ́n; má ṣe pa á tì sápá kan.
34
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetí sílẹ̀ sí mi, tí ń sọ́nà ní ẹnu ọ̀nà mi lójoojúmọ́, tí ń dúró ní ẹnu ọ̀nà mi.
35
Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè ó sì rí ojú rere gbà lọ́dọ̀ OLÚWA.
36
Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára gbogbo ẹni tí ó kórira mi fẹ́ ikú.”
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31