bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 27
Proverbs 27
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 28 →
1
Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé.
2
Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ àní ẹlòmíràn, kì í ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ.
3
Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo ṣùgbọ́n ìmúbínú un aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ.
4
Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀ ṣùgbọ́n tani ó le è dúró níwájú owú?
5
Ìbániwí gbangba sàn ju ìfẹ́ ìkọ̀kọ̀ lọ.
6
Ọgbẹ́ láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ṣùgbọ́n ọ̀tá máa ń fẹnu-koni-lẹ́nu púpọ̀.
7
Kódà oyin kò dùn lẹ́nu ẹni tí ó ti yó ṣùgbọ́n òróòro gan an dùn lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.
8
Bí ẹyẹ tí ó ṣáko lọ kúrò níbi ìtẹ́ rẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣáko lọ kúrò ní ilé rẹ̀.
9
Ìpara olóòórùn dídùn àti tùràrí ń mú ayọ̀ wá sínú ọkàn bẹ́ẹ̀ ni inú dídùn láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ ń wá láti inú ìmọ̀ràn tí ó Ṣàkóso.
10
Má ṣe kọ ọ̀rẹ́ rẹ àti ọ̀rẹ́ baba rẹ sílẹ̀, má sì ṣe lọ sílé arákùnrin rẹ nígbà tí ìdàámú dé bá ọ ó sàn kí o jẹ́ aládúúgbò tí ó súnmọ́ ni ju arákùnrin tí ó jìnnà síni.
11
Gbọ́n, ọmọ mi, kí o sì mú ayọ̀ wá sínú ọkàn mi nígbà náà ni mo le dá gbogbo ẹni tí ó bá kẹ́gàn mi.
12
Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pamọ́ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí kàkàkí ó dúró ó tẹ̀ṣíwájú, ó sì jìyà rẹ̀.
13
Gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àjòjì fi ṣe ẹ̀rí ìdúró bí o bá ṣe onídùúró fún obìnrin oní ìṣekúṣe.
14
Bí ènìyàn kan ń kígbe e ṣúre fún aládùúgbò rẹ ní òwúrọ̀ a ó kà á sí bí èpè.
15
Àyà tí ó máa ń jà dàbí ọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;
16
dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kun tàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.
17
Bí irin tí ń pọ́n irin mú bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.
18
Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èṣo rẹ̀ ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.
19
Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò ó bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.
20
Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.
21
Iná fún fàdákà iná ìlérú fún wúrà, ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.
22
Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó, fi ọmọ odó gún-un bí èlùbọ́ ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀.
23
Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà bojú tó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára;
24
nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.
25
Nígbà tí a bá kó koríko jọ láti orí òkè
26
àwọn àgùntàn yóò pèṣè aṣọ fún ọ, àti ewúrẹ́ yóò pèṣè owó oko.
27
Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíkì ewúrẹ́ láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31