bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 29
Proverbs 29
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 30 →
1
Ẹni tí ó sì ń ṣorí kunkun lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe.
2
Nígbà tí olódodo bá ń gbilẹ̀, àwọn ènìyàn a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn ń kórìíra.
3
Ènìyàn tí ó fẹ́ràn ọgbọ́n mú kí baba rẹ̀ láyọ̀ ṣùgbọ́n ẹni ti ń bá aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́ ba ọrọ̀ ọ rẹ̀ jẹ́
4
Nípa ìdájọ́ òdodo ni ọba fi í mú ìlú tòrò nini, ṣùgbọ́n èyí tí ń ṣojúkòkòrò àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fà á lulẹ̀.
5
Ẹnikẹ́ni tí ó bá tan aládúgbò rẹ̀ ó ń dẹ àwọ̀n de ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀.
6
Ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn ibi ni ó jẹ́ ìdẹkùn rẹ̀ ṣùgbọ́n olódodo le è kọrin kí ó sì máa yọ̀.
7
Olódodo ń ṣaápọn nípa ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn tálákà, ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó kan ènìyàn búburú nínú irú rẹ̀.
8
Àwọn Ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.
9
Bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn bá lọ sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aláìgbọ́n aláìgbọ́n a máa bínú a sì máa jà, kò sì ní sí àlàáfíà.
10
Àwọn tí ó ń tàjẹ̀ sílẹ̀ kòrí ẹni-dídúró-ṣinṣin wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa olódodo.
11
Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹ̀nú rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.
12
Bí olórí bá fetí sí irọ́, gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ a di ènìyàn búburú lójú rẹ̀.
13
Tálákà ènìyàn àti aninilára jọ ní àbùdá yìí, OLÚWA jẹ́ kí ojú àwọn méjèèjì máa ríran.
14
Bí ọba kan bá ń ṣe ìdájọ́ talákà pẹ̀lú òtítọ́ ìtẹ́ ìjọba rẹ yóò fìdí múlẹ̀ nígbà gbogbo.
15
Ọ̀pá ìbániwí ń fún ni ní ọgbọ́n ṣùgbọ́n ọmọ tí a fi sílẹ̀ fúnra rẹ̀ a dójú ti ìyá rẹ̀.
16
Nígbà tí ènìyàn búburú ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ ń gbilẹ̀ ṣùgbọ́n Olódodo yóò rí ìṣubú wọn.
17
Bá ọmọ rẹ wí, yóò sì fún ọ ní àlàáfíà yóò sì mú inú dídùn wá sí inú ọkàn rẹ.
18
Níbi tí kò ti sí ìfihàn, àwọn ènìyàn a gbé ìgbé ayé àìbìkítà. Ṣùgbọ́n ìbùkún ní fún àwọn tí ń pa òfín mọ́.
19
A kò le fi ọ̀rọ̀ lásán kìlọ̀ fún ìránṣẹ́ bí ó tilẹ̀ yé e, kò ní kọbi-ara-síi.
20
Njẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀? Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.
21
Bí ènìyàn kan bá kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lákẹ̀ẹ́jù láti kékeré yóò mú ìbànújẹ́ wá ní ìgbẹ̀yìn.
22
Oníbìínú ènìyàn a ru ìjà sókè, Onínú-fùfù ènìyàn a sì máa dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.
23
Ìgbéraga ènìyàn a máa sọ ọ́ di ẹni ilẹ̀ ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn a máa gba iyì kún iyì.
24
Ẹni tí ó ń ran olè lọ́wọ́ gan an ni ọ̀ta rẹ̀ O ń gbọ́ epe olóhun kò sì le è fọhùn.
25
Ìbẹ̀rù ènìyàn kan yóò sì di ìdẹkùn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bẹ̀rù OLÚWA wà láìléwu.
26
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ń wá ojúrere alákòóṣo, ṣùgbọ́n láti ọdọ OLÚWA ni ènìyàn tí ń gba ìdájọ́ òdodo.
27
Olódodo kórìíra àwọn aláìsòótọ́: ènìyàn búburú kórìíra olódodo.
← Chapter 28
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 30 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31