bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 5
Proverbs 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 6 →
1
Ọmọ mi, fiyè sí ọgbọ́n ọ̀n mi tẹ́tí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ àròjinlẹ̀ mi
2
kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
3
Nítorí ètè alágbèrè aṣẹ́wó obìnrin a máa ṣun oyin, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ
4
ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìngbẹ́yín, ó korò ju òróòro lọ ó mú bí idà olójú méjì.
5
Ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú ìgbéṣẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
6
Kò tilẹ̀ ronú nípa ọ̀nà ìyè ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
7
Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ tẹ́tí sí mi má ṣe yàgò kúrò nínú àwọn nǹkan tí mo sọ
8
Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà síi dáadáa má ṣe súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀
9
àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo agbára rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn
10
kí àwọn àjòjì ó má baà fi ọrọ̀ rẹ ṣara rindin kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
11
Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora, nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán
12
Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ọkàn mi ṣe wá kóòríra ìbáwí!
13
N kò gbọ́ràn sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu, tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
14
Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátapáta ní àárin gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
15
Mu omi láti inú un kànga tìrẹ Omi tí ń ṣàn láti inú kànga rẹ.
16
Ó ha yẹ kí omi ìṣun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà àti odò tí ń sàn lọ sí àárin ọjà?
17
Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan, má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjòjì láéláé.
18
Ǹjẹ́, kí oríṣun rẹ di àbùkù fún; kí ó sì yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
19
Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn nígbà gbogbo jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ̀ máa fà ọ́ títí láéláé
20
Ọmọ mi, èéṣe tí ìfẹ́ aṣẹ́wó fi ń fà ọ́ tí ìwọ sì ń dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?
21
Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò farasin rárá fún OLÚWA Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀wò
22
Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn; okùn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀ dì í le kankan
23
Yóò kú nítorí àìgba ẹ̀kọ́ ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ ló mú kó ṣáko lọ.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31