bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 28
Proverbs 28
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 29 →
1
Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.
2
Nígbà tí orílẹ̀ èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀ ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́
3
ọba tí ó ni àwọn talákà lára dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ẹ̀gbìn lọ.
4
Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.
5
Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibi ṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá OLÚWA dáradára.
6
Ó sàn láti jẹ́ talákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkù ju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.
7
Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọ ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójú ti baba rẹ̀.
8
Ẹni tí ó mú ọrọ̀ rẹ̀ di púpọ̀ nípa èrè àjẹjù ń kó o jọ fún ẹlòmìíràn, tí yóò ní àánú àwọn talákà.
9
Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin, kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra.
10
Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere.
11
Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n talákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.
12
Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora.
13
Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì í ṣe rere, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.
14
Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ó bẹ̀rù OLÚWA nígbà gbogbo ṣùgbọ́n ẹni tí ó ṣé ọkàn rẹ̀ le bọ́ sínú wàhálà.
15
Bí kìnnìún tí ń ké tàbí Béárì tí ń halẹ̀ ni ènìyàn búburú tí ń jọba lórí àwọn aláìlágbára.
16
Ọba tí ó jẹ gàba lórí ìlú láì gbàmọ̀ràn kò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra èrè ìjẹkújẹ yóò gbádùn ọjọ́ gígùn.
17
Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn yóò máa joró rẹ̀ títí ikú má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ràn án lọ́wọ́.
18
Ẹni tí ìrìn rẹ̀ kò ní àbùkù wà láìléwu ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ayípadà yóò ṣubú lójijì.
19
Ẹni tí ó bá ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ lọ́pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ń lé ohun aṣán yóò kún fún òsì.
20
Olóòótọ́ ènìyàn yóò rí ìbùkún gbà gan an ṣùgbọ́n ẹni tí ojú ń kán láti di ọlọ́rọ̀ kì yóò lọ, láìjìyà.
21
Ojúṣááj ú ṣíṣe kò dára ṣíbẹ̀ ènìyàn kan ń ṣẹ̀ nítorí òkèlè oúnjẹ kan.
22
Ahun ń sáré àti là kò sì funra pé òsì dúró de òun.
23
Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojú rere síi nígbẹ̀yìn ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ.
24
Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè tí ó sì wí pé “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀” irú kan ni òun àti ẹni tí ń panírun.
25
Ọ̀kanjúà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA yóò gbilẹ̀.
26
Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu.
27
Ẹni tí ó ń fifún talákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.
28
Nígbà tí ènìyàn búburú bá dórí ìjọba, àwọn ènìyàn a na pápá bora; ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú bá ṣègbé, àwọn olódodo ń gbilẹ̀ síi.
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 29 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31