bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 15
Proverbs 15
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 16 →
1
Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padà ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.
2
Ahọ́n ọlọgbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jáde ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.
3
Ojú OLÚWA wà níbi gbogbo, Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.
4
Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyè ṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.
5
Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọgbọ́n.
6
Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.
7
Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀; ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.
8
OLÚWA kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ẹ lọ́rùn.
9
OLÚWA kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.
10
Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an, ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.
11
Ikú àti ìparun sí sílẹ̀ níwájú OLÚWA mélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.
12
Ẹlẹ́gàn kórìíra ìbáwí: kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.
13
Inú dídùn máa ń mú kí ojú túká ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ọkàn máa ń pa ẹ̀mí run.
14
Ọkàn olóye ń wá ìmọ̀ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń fẹ́ ìwà òmùgọ̀ bí ẹní jẹun.
15
Gbogbo ọjọ́ àwọn olùpọ́njú jẹ́ ibi, ṣùgbọ́n ọkàn tí ń dunnú a máa Jàṣè ṣáá.
16
Ó sàn kí ó má pọ̀, kí ìbẹ̀rù OLÚWA sì wà ju ọrọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú ìyọnu.
17
Oúnjẹ ewébẹ̀ níbi tí ìfẹ́ wà sàn ju àbọ́pa màlúù tòun ti ìríra.
18
Ènìyàn onínú ríru dá ìjà sílẹ̀ ṣùgbọ́n onísùúrù paná ìjà.
19
Ẹ̀gún dí ọ̀nà ọ̀lẹ ṣùgbọ́n pópónà tí ń dán ni ti àwọn dídúró ṣinṣin.
20
Ọlọgbọ́n ọmọ mú inú baba rẹ̀ dùn, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ọmọ kẹ́gàn baba rẹ̀.
21
Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀; ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà.
22
Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn; ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràwà.
23
Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó báa mu ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!
24
Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọgbọ́n láti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú.
25
OLÚWA fa ilé onígbéraga ya lulẹ̀, Ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó mọ́ láìyẹ̀.
26
OLÚWA kórìíra èrò ènìyàn búburú,
27
Ọ̀kánjúwà ènìyàn mú ìyọnu bá ilé rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò yè.
28
Ọkàn olódodo ń wọn ìdáhùn wò ṣùgbọ́n ẹnu ènìyàn búburú ń tú ibi jáde.
29
OLÚWA jìnnà sí ènìyàn búburú ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.
30
Ojú tó túká máa ń mú ayọ̀ wá fún ọkàn, ìròyìn ayọ̀ sì ń mú ìlera wá sínú egungun.
31
Ẹni tí ó fetí sí ìbáwí tí ń fún ni ní ìyè, yóò wà ní àpéjọpọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n.
32
Ẹni tí ó kọ̀ ìbáwí kẹ́gàn ara rẹ̀, Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí yóò ní ìmọ̀ síi.
33
Ìbẹ̀rù OLÚWA kọ́ ènìyàn ní ọgbọ́n, Ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 16 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31