bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 24
Proverbs 24
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 25 →
1
Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;
2
Nítorí ọkàn wọn ń gbérò ohun búburú, ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.
3
Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́ nípa òye sì ni ó ti fìdí múlẹ̀;
4
Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.
5
Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀, ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára síi
6
Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà: nínú ìsẹ́gún ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.
7
Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.
8
Ẹni tí ń pète ibi ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.
9
Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.
10
Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!
11
Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ síbi ikú là; fa àwọn tó ń ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n lọ síbi ìparun padà.
12
Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkankan nípa èyí,” ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsíi? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́? Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?
13
Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára, oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
14
Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ ìrètí rẹ kì yóò sì já sófo.
15
Má ṣe ba ní ibùba bí i arúfin dé ilé Olódodo, má ṣe kó ibùgbé è rẹ̀ lọ;
16
Nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà méje, yóò tún padà dìde ṣáá ni, ṣùgbọ́n ìdàámú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.
17
Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú; nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀
18
àìṣe bẹ́ẹ̀ OLÚWA yóò rí i yóò sì bínú yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
19
Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,
20
nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.
21
Bẹ̀rù OLÚWA àti ọba, ọmọ mi, má sì ṣe dara pọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun
22
nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn, ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?
23
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n láti ṣe ojúṣàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá:
24
Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre” àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
25
Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi, ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.
26
Ìdáhùn òtítọ́ ó dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu.
27
Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára; lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.
28
Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládúgbò rẹ láìnídìí, tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
29
Má ṣe wí pé, “Mà á ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi; Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”
30
Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ, mo kọjá níbi oko aláìgbọ́n ènìyàn;
31
ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo, koríko ti gba gbogbo oko náà
32
Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsí mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;
33
oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi
34
Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè àti àìní bí olè.
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 25 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31