bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 30
Proverbs 30
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 29
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 31 →
1
Àwọn ọ̀rọ̀ Ágúrì ọmọ Jákè, ọ̀rọ̀ ìṣọtẹ́lẹ̀ tí ọkùnrin yìí sọ fún Ítíélì, sí Ítíélì àti sí Úkálì:
2
“Èmi ni aláìmòye ju nínú àwọn ènìyàn; N kò ní òye ènìyàn.
3
Èmi kò tilẹ̀ kọ́ ọgbọ́n tàbí ní ìmọ̀ ẹni mímọ́ nì
4
Ta ni ó ti gòkè lọ sí ọ̀run tí ó sì padà sọ̀kalẹ̀? Ta ni ó ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ihò àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀? Ta ni ó ti ta kókó omi sétí aṣọ? Ta ni ó fi gbogbo ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀? Kí ni orúkọ rẹ̀, àti orúkọ ọmọ rẹ̀? Sọ fún mi bí o bá mọ̀.
5
“Gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ aláìlábùkù; oun ni ààbò fún gbogbo ẹni fi í ṣe ibi ìpamọ́ wọn
6
Má ṣe fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò bá ọ wí yóò sì sọ ọ́ di òpùrọ́.
7
“Ohun méjì ni mo ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ, OLÚWA; má ṣe fi wọ́n dù mí kí ń tó kú:
8
Mú èké ṣíṣe àti irọ́ jìnnà sí mi; má ṣe fún mi ní òsì tàbí ọrọ̀, ṣùgbọ́n fún mi ní oúnjẹ òòjọ́ mi nìkan,
9
Àìṣe bẹ́ẹ̀, mo lè ní àníjù kí n sì gbàgbé rẹ kí ń sì wí pé, ‘Ta ni OLÚWA?’ Tàbí kí ń di òtòsì kí ń sì jalè kí ń sì ṣe àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run mi.
10
“Má ṣe ba ìránṣẹ́ lórúkọ jẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò ṣẹ́ èpè lé ọ. Ìwọ yóò sì jìyà rẹ̀.
11
“Àwọn kan wá ṣépè fún àwọn baba wọn tí wọn kò sì ṣúre fún àwọn ìyá wọn:
12
Àwọn tí ó mọ́ ní ojú ara wọn ṣíbẹ̀ tí wọn kò sì mọ́ kúrò nínú èérí wọn;
13
Àwọn ẹni tí ojú wọn gbéga nígbà gbogbo, tí ìwolẹ̀ wọn sì kún fún ìgbéraga.
14
Àwọn ẹni tí eyín wọn jẹ́ idà Àwọn tí èrìgì wọn kún fún ọ̀bẹ láti jẹ àwọn talákà run kúrò ní ilẹ̀ ayé àwọn aláìní kúrò láàrin àwọn ọmọ ènìyàn.
15
“Eṣúṣú ni ọmọbìnrin méjì ‘Múwá! Múwá!’ ní wọn ń ké. “Àwọn nǹkan mẹ́ta kan wà tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn láéláé, mẹ́rin tí kò jẹ́ wí láéláé pé, ‘Ó tó’:
16
Ibojì, inú tí ó yàgàn, ilẹ̀, tí omi kì í tẹ́lọ́rùn láéláé, àti iná, tí kì í wí láéláé pé, ‘Ó tó!’
17
“Ojú tí ń fi baba ṣẹ̀fẹ̀, tí ó kẹ́gàn ìgbọràn sí ìyá ẹyẹ àkálá ẹ̀bá odò ni yóò yọ ọ́, igún yóò mú un jẹ.
18
“Àwọn nǹkan mẹ́ta wà tí ó jẹ́ ìyàlẹ́nu fún mi, mẹ́rin tí kò yé mi:
19
Ipa idì ní òfuurufú ipa ejò lórí àpáta ipa ọkọ̀ ojú omi lójú agbami òkun àti ipa ọ̀nà ọkùnrin tí ó mú wúndíá lọ́wọ́.
20
“Èyí ni ọ̀nà alágbérè obìnrin ó jẹun o sì nu ẹnu rẹ̀ ó sì wí pé, N kò ṣe ohunkóhun tí kò tọ́.
21
“Lábẹ́ nǹkan mẹ́ta ni ile ayé ti ń wárìrì lábẹ́ ohun mẹ́rin ni kò ti lè mí fín ín.
22
Ìránṣẹ́ tí ó di Ọba aláìgbọ́n tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ́
23
Obìnrin tí gbogbo ènìyàn kórìíra tí ó sì wá lọ́kọ ìránṣẹ́bìnrin tí ó gbọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.
24
“Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi;
25
Àwọn èrà jẹ́ ẹ̀dá tí ó ní agbára díẹ̀ síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò
26
Ehoro jẹ́ ẹ̀dá tí kò ní agbára púpọ̀ ṣíbẹ̀ wọ́n ń ṣe ilé wọn sí ibi ihò àpáta;
27
Eṣú kò ní ọba ṣíbẹ̀ wọ́n ń jáde lọ papọ̀ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́
28
a lè fi ọwọ́ mú aláǹgbá ṣíbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.
29
“Àwọn ohun mẹ́ta ní n bẹ tí ń rìn rere, ohun mẹ́rin tí ń kọrí sí ibi rere,
30
Kìnnìún, alágbára láàrin ẹranko tí kì í sá fún ohunkóhun
31
Ẹsin tí a dì lẹ́gbẹ̀ẹ́; àti òbúkọ, àti ọba pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láyìíká rẹ̀.
32
“Bí ìwọ bá ti hùwà aṣiwèrè nípa gbígbé ara rẹ ga, tàbí tí o bá ti gbèrò ibi, da ọwọ́ rẹ bo ẹnu rẹ!
33
Nítorí bí fífún omi ọmú tí í mú wàrà wá tí fífún imú sì ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde bẹ́ẹ̀ ni rírú ìbínú sókè í mú ìjà wá.”
← Chapter 29
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 31 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31