bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Proverbs 13
Proverbs 13
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 14 →
1
Ọlọ́gbọ́n ọmọ pa àṣẹ baba rẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n ẹlẹ́gàn kò fetí sí ìbáwí.
2
Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ènìyàn ń gbádùn àwọn ohun rere ṣùgbọ́n, aláìsòótọ́ ní ìfẹ́ ọkàn láti inú ìwà ipá.
3
Ẹnikẹ́ni tí ó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ pa ẹnu ara rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ gbàù-gbàù yóò parun.
4
Ọkàn ọ̀lẹ ń fẹ́, ṣùgbọ́n kò rí nǹkankan, ṣùgbọ́n ọkàn àwọn ti kì í ṣọ̀lẹ rí ìtẹ́lọ́rùn.
5
Olódodo kórìíra ohun tí í ṣe irọ́ Ṣùgbọ́n ènìyàn búburú hu ìwà ìríra àti ìtìjú.
6
Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòótọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú sí ẹlẹ́ṣẹ̀ nípò.
7
Ènìyàn kan díbọ́n bí ẹni tí ó ní ọrọ̀ síbẹ̀ kò ní nǹkankan ẹlòmííràn díbọ́n bí i talákà, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
8
Ọrọ̀ ènìyàn le è ra ẹ̀mí rẹ̀ ṣùgbọ́n talákà kì í gbọ́ ìdẹ́rùbà.
9
Ìmọ́lẹ̀ olódodo tàn roro, ṣùgbọ́n àtùpà ènìyàn búburú ni a pa kú.
10
Ìgbéraga máa ń dá ìjà sílẹ̀ ni ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà nínú àwọn tí ń gba ìmọ̀ràn.
11
Owó tí a fi ọ̀nà èrú kó jọ yóò sí lọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ń kó owó jọ díẹ̀ díẹ̀ yóò pọ̀ síi.
12
Ìrètí tí ń falẹ̀ máa ń mú kí ọkàn ṣàárẹ̀ ṣùgbọ́n ìrètí tí a rí gbà jẹ́ igi ìyè.
13
Ẹni tí ó kẹ́gàn ẹ̀kọ́ yóò jìyà rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa àṣẹ mọ́ gba èrè rẹ̀.
14
Ìkọ́ni ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìdẹkùn ikú.
15
Òye pípé ń mú ni rí ojú rere Ṣùgbọ́n ọ̀nà aláìsòótọ́ kì í tọ́jọ́.
16
Gbogbo olóye ènìyàn máa ń hùwà pẹ̀lú ìmọ̀ Ṣùgbọ́n aláìgbọ́n a fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.
17
Ìránṣẹ́ búburú bọ́ sínú ìdàámú ṣùgbọ́n aṣojú olóòtọ́ mú ìwòsàn wá.
18
Ẹni tí ó kọ ìbáwí yóò di talákà yóò sì rí ìtìjú, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí ni yóò rí ọlá.
19
Ìfẹ́ tí a múṣẹ dùnmọ́ ọkàn ṣùgbọ́n ìríra ni fún aṣiwèrè láti kúrò nínú ibi.
20
Ẹni tí ó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń bá aláìgbọ́n kẹ́gbẹ́ ń pa ara rẹ̀ lára.
21
Òsì a máa ta ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọrọ̀ ni èrè fún olódodo.
22
Ènìyàn rere a máa fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n, a kó ọrọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pamọ́ fún àwọn olódodo.
23
Ilẹ̀ ẹ talákà le è mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irè oko wá ṣùgbọ́n àìsòdodo gbá gbogbo rẹ̀ lọ.
24
Ẹni tí ó fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ yóò máa báa wí.
25
Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31